Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORÍ — KẸWÀÁ ÀWỌN ÌLÀNÀ

    Ilé Dé Ilé

    Ní àwọn ìlú ń lá ń lá àwọn ẹgbẹ́ kan wà tí a kò lè bá pàdé nínú ìpàdé ìta gbangba. Àwọn wọ̀nyí ni a gbọdọ̀ wá bí olùṣọ́ àgùtàn ṣe ń wá àgùtàn a rẹ̀ tí ó sọnù. Àìsinmi, ìgbìyànjú ní ọlọ́danni ni a gbọdọ̀ lò nípa a wọn. Nígbà tí ọlọ́danni bá fi iṣẹ́ ẹ rẹ̀ sílẹ̀ láì ṣe, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfààní ni yóò pàdánù, tí ó bá jẹ́ pé, wọ́n ṣàtúnṣe, yóò mú ìtẹ̀síwájú bá iṣẹ́ bí ó ṣe pinnu.-Testimonies, vol.9, p.111.IIO 113.1

    Àwọn ìṣe àti àwọn ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ni a nílò. Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ Krístì ni fifún ni ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ RẸ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìfẹ́ àti ìtọrẹ àánú. Jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ lọ láti ojúlé dé ojúlé, kí wọn ṣè rànwọ́ níbi tí wọ́n bá ti nílò ìrànlọ́wọ́ ọ wọn, àti níbi tí ànfààní bá ti ṣí sílẹ̀ fún wọn. Kí wọn sọ ìtàn a ti àgbélébù ú fún wọn. Kristi ni ó ní láti jẹ́ ìpilẹ̀sẹ̀ ọ̀rọ̀ ọ wọn. Wọn kò nílò láti gùnlé àwọn àkòrí ìkọ́ni; jẹ́ kí wọn sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ àti ìrúbọ ọ ti Kristi. Jẹ́ kí wọn di òdodo o RẸ̀ mú, kí wọn fi mímọ́ ọ RẸ̀ hàn nínú ìgbé ayé e wọn.- Testimonies, vol.7, p.228.IIO 113.2

    Ọlọrun kì í ṣe ojú ṣàájú. Yóò lo onírẹ̀lẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ tí ó jẹ́ olùfọkànsìn, bí wọn kò tilẹ̀ tí ì ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó bẹ́ẹ̀ bí àwọn mìíràn. Jẹ́ kí irú àwọn wọ̀nyí kópa nínú iṣẹ́ ìsìn fún-Un nípa ṣíṣe iṣẹ́ ojúlé dé ojúlé. Wọ́n lè jòkó ní ẹ̀bá iná, tí wọ́n bá jẹ́- onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n bá lóye, tí wọ́n bá sì jẹ́ oníwà bí Ọlọ́run- wọ́n lè ṣe púpọ̀ láti bá àìní àwọn ìdílé gangan pàdé ju ti àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tí a gbọ́wọ́ lé lórí.- Testimonies, vol.7, p. 21.IIO 113.3

    Láarin àwọn ọmọ ìjọ ọ wa iṣẹ́ ojúlé dé ojúlé, gbọdọ̀ pọ̀ sí i, nípa fífún wọn ní àwọn Bibeli kíkà àti pínpín àwọn ìwé àkójọ oríṣiríṣi.- Testimonies, vol.9, p. 127. IIO 113.4

    Gbogbo àwọn tí wọ́n bá kópa nínú iṣẹ́ ojúlé dé ojúlé yóò rí àwọn ànfààní ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Wọ́n gbọdọ̀ gbàdúrà fún aláìsàn, wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe ohun tí ó bá wà ní ìkáwọ́ ọ wọn láti mú ìrọ̀rùn bá wọn nínú ìnira a wọn. Wọ́n gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ láarin àwọn onírẹ̀lẹ̀, aláìní, àti àwọn tí a pọ́n lójú. A gbọdọ̀ gbàdúrà fún àti pẹ̀lú àwọn aláìní olùrànlọ́wọ́ tí wọn kò ní agbára ti ara a wọn láti kó ara wọn ní ìjánu nípa ohun jíjẹ tí ìfẹ́kúfẹ̀ ẹ́ ti ara ti sọ di yẹpẹrẹ. Ìtara, ìgbìyànjú ìforítì ni a gbọdọ̀ ṣe fún ìgbàlà àwọn tí ìfẹ́ ọkàn- an wọn sọjí. A lè bá àwọn mìíràn pàdé nípa iṣẹ́ àánú tí kò wá ti ara a rẹ̀. Ohun tí wọ́n nílò lára ni a kọ́kọ́ gbọdọ̀ fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Tí wọ́n bá rí ẹ̀rí nípa ìfẹ́ àimọ- tara-ẹni-nìkan yóò rọrùn fún wọn láti gbàgbọ́ nínú ìfẹ́ ẹ Kristi.- Tvstimonies, vol.6, pp.83,84.IIO 114.1

    Jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ lọ láti ojúlé dé ojúlé, kí wọn ṣí Bibeli fún àwọn eniyan, kí wọn pín àwọn ìkéde, kí wọn sọ fún àwọn mìíràn nípa ìmọ́lẹ̀ tí ó ti bùkún àwọn ọkàn-an wọn.- Testimonies, vol.9, p.123.IIO 114.2

    Olùgbàlà a wa lọ láti ojúlé dé ojúlé, Ó ń wo aláìsàn sàn, Ó ń tu àwọn oníròbìnújẹ́ nínú, Ó ń tu àwọn tí a ni lára lára, Ó ń sọ̀rọ̀ àlááfìà fún àwọn tí ó ní ìbìnújẹ́. Ó gbé àwọn ọmọdé sí apá a RẸ̀, Ó súre fún wọn, Ó sọ̀rọ̀ ìrètí àti ìtùnú fún àwọn ìyá tí àárẹ̀ mú. Pẹ̀lú ìyọ́nú àti ìwà tútù tí kì í yẹ̀, Ó bá onírúurú ìbànújẹ́ àti ìpọ́njú àwọn ènìyàn pàdé.IIO 114.3

    Kì í ṣe fún ara a RẸ̀, bíkòṣe fún àwọn tí ó ti ṣiṣẹ́ fún. Ó jẹ́ ìránṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn. Ara a RẸ̀ àti ohun mímu ni ó mú ìrètí àti agbára bá àwọn tí ó ṣalábápàdé e RẸ̀.- Gospel Workers, p.188.IIO 114.4

    Gbígbé òtítọ́ kalẹ̀, nínú ìfẹ́ àti inú kan láti ojúlé dé ojúlé, jẹ́ ìṣe déédé pẹ̀lú àṣẹ tí Ọlọ́run fún àwọn àtẹ̀lé e RẸ̀ nígbà tí ó rán wọn jáde lọ nínú iṣẹ́ ìhìnrere àkọ́kọ́. Nípa àwọn orin ìyìn, nípa ìrẹ̀lẹ̀, àdúrà gbígbà tọkàn tọkàn, ọ̀pọ̀ ni wọn yóò bá pàdé. Òṣìṣẹ́ ọ̀run náà yóò wà níbẹ̀ láti fi ìdálẹ́bi nípa ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ọkàn. “Èmi wà pẹ̀lú u yín nígbà gbogbo,” ni ìlérí i RẸ̀. Pẹ̀lú ìdánilójú wíwà pẹ̀lú olùrànlọ́wọ́ yìí, a lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìrètí àti ìgboyà.- Testimonies, vol.9, p.34.IIO 114.5

    Àwọn òṣìṣẹ́ ojúlé dé ojúlé ni a nílò. Olúwa ń pè ìpè fún pín- pinnu ìgbìyànjú láti lọ sí ibi gbogbo níbi tí àwọn ènìyàn kò tí ì mọ̀ nípa òtítọ́ ọ ti Bibeli. Kíkọrin àti gbígbàdúrà àti Bibeli kíkà ni a nílò nínú ilé àwọn ènìyàn. Ní báyìí àní níbáyìí, àsìkò nìyí i fún wa láti gbọ́ràn sí àṣẹ ẹ RẸ̀ “Kọ́ wọn láti pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún- un yin”. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ yìí ti gbọdọ̀ ní ìmọ̀ ọ ti Bíbélì. “A ṣá à ti kọ ọ́” ni ó gbọdọ̀ jẹ́ ohun ìjà ààbò o wọn. - Counsels to Teachers, p.540.IIO 114.6

    Ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ẹ bẹ àwọn tí wọ́n ń gbé nítòsí i yín wò, nípa bíbákẹ́dùn àti inú rere wá láti dé àwọn ọkàn-an wọn. Ní ìdánilójú láti ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà tí yóò fi mú ẹ̀tanú kúro dípò kí ó dá kún-un. Kí o sì rántí pé àwọn tí wọ́n bá mọ òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí, síbẹ̀ tí wọ́n fi ààlà sí àwọn ìgbìyànjú u wọn sí àwọn ìjọ ọ wọn, tí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ fún àwọn aládúgbò o wọn tí wọn kò tí i yípadà ni a yóò pè láti ṣírò fún àwọn iṣẹ́ tí wọn kò tí ì mú ṣe. - Testimonies, vol.9, p.34.IIO 115.1

    Ní ìrìn-àjò àkọ́kọ́ yìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní láti lọ síbi tí Jesu ti ´dé rí tẹ́lẹ̀, tí ó sì ní àwọn ọ̀rẹ́. Ìpalẹ̀mọ́ fún ìrìn-àjò náà ni ó rọrùn jù. Kò sí ohun tí ó gbọdọ̀ yí ọkàn-an wọn kúrò nínú iṣẹ́ ń lá a wọn, tàbí ní ọ̀nàkọnà tí ó lè rú àtakò sókè kí ó sì tilẹ̀kùn iṣẹ́ tí wọ́n ní láti ṣe níwájú. Wọn kò ní láti gba aṣọ ti àwọn olùkọ ẹ̀sìn, tàbí lo ìrísí aṣọ láti mú wọn yàtọ̀ sí àwọn àgbẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ yìí. Wọn kò nílò láti wọ inú àwọn Sínágọ́ọ̀gù lọ kí wọn pe àwọn ènìyàn papọ̀ fún iṣẹ́ ìta gbangba; Ìgbìyànjú u wọn ni wọ́n ní láti mú lọ sí iṣẹ́ ojúlé dé ojúlé. Wọn kò nílò láti fi àsìkò ṣòfò nínú ìkíní àìnídì í, tàbí nínú u lílọ láti ojúlé dé ojúlé fún àsè àpèjẹ. Ṣùgbọ́n níbì kọ̀ọ̀kan wọ́n ní láti gba àwọn tí wọ́n yẹ láti ṣe wọ́n lálejò, àwọn tí yóò kí wọn káàbọ̀ tọkàn tọkàn bí ìgbà tí wọn ń gba Kristi fúnra a Rẹ̀ lálejò. Wọ́n ní láti wọ ibùgbé e wọn pẹ̀lú ìkíni tí ó dára, “Àlàáfíà fún ilé yìí”. Ilé yóò sì ní ìbùkún pẹ̀lú àwọn àdúra a wọn, orin ìyìn lógo, àti ṣíṣí inú ìwé mímọ́ ní àyíká ìdílé.- The Desire of Ages, pp.351,352.IIO 115.2

    Bẹ àwọn aládúgbò o rẹ̀ wò ní ọ̀nà tí o lè fi bá wọn dọ́rẹ̀ ẹ́, kí o sì di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú u wọn….Àwọn tí kò bá gba iṣẹ́ yìí, àwọn tí wọn kópa pẹ̀lú ìdágunlá pé àwọn kan ti ní ìṣipayá, yóò sọ ìfẹ́ àkọ́kọ́ ọ wọn nù láìpẹ́, wọn yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí í ìbáwí, òfintótó, àti ìdálẹ́bi fún àwọn ará a wọn.Review and Herald, May 13, 1902.IIO 115.3

    Ìgbìyànjú àwọn àpóstélì kì í ṣe ti ìpìlẹ̀ sí sísọ̀rọ̀ ní ìta gbangba; ọ̀pọ̀ ló wà tí wọn kò lè bá pàdé ní ọ̀nà yìí. Ó lo ọ̀pọ̀ àkókò nínú iṣẹ́ ojúlé dé ojúlé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣànfààní nínú ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ níti àyíká ilé. Ó bá aláìsàn àti àwọn oníròbìnújẹ́ wò, Ó ń tu àwọn tí a ní lára nínú, Ó sì gbé àwọn tí a pọ́n lójú sókè. Nínú gbogbo ohun tí Ó sọ àti ohun tí Ó ṣe, ó gbé orúkọ Jésù ga.Báyìí ó ṣiṣẹ́, “nínú àìlera, àti nínú ìbẹ̀rù, àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì”.Ó wárìrì kí ìkọ́ni i rẹ̀ má ṣe ìfihàn-a ti ènìyàn dípò o ti Ọlọ́run. - The Acts of the Apostles, p.250.IIO 116.1

    Lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn aládúgbò ò rẹ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí o sì súnmọ́ wọn títí tí ọkàn-an wọn yóò fi gbóná nípa ìfẹ́ àìmọ- tara- ẹni- nìkan-àn rẹ. Ṣe ìbákẹ́dùn pẹ̀lú u wọn, gbàdúrà pẹ̀lú u wọn, ṣọ́ àwọn ààyè láti ṣe wọ́n ní rere ó ṣe le ṣe é ṣe, kó àwọn díẹ̀ jọ kí o sì ṣí ọ̀rọ̀ Ọlọrun sí àwọn ọkàn tí ó dúdú. Má a ṣọ́ra, bí ẹni tí ó gbọdọ̀ ṣe ìṣirò fún àwọn ọkàn eniyán, kí o sì lo gbogbo àwọn ànfààní tí Ọlọrun fún ọ níti sí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú u RẸ̀ nínú ọgbà àjàrà ẹ̀kọ́ ọ RẸ̀. Má ṣe àìbìkítà ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn aládúgbò ò rẹ, nínú agbára à rẹ, ṣe inú rere sí wọn, pé ìwọ “ní gbogbo ọ̀nà o lè gba ẹnìkan là”. A nílò láti wá ẹ̀mí tí ó ń rọ Pọ́ọ̀lù àpóstélì láti lọ sí ojúlé dé ojúlé tí ó ń bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú omijé, tí ó ń kọ́ni ˆÌrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ìgbàgbọ́ sí Jésù Krístì Olúwa a wa”. - Review and Herald, March 13, 1888.IIO 116.2

    Oluwa ti gbé e ka iwájú ù mi iṣẹ́ tí a ní láti ṣe ní àwọn ìlú ń lá ń lá. Àwọn onígbàgbọ́ nínú àwọn ìlú ń lá ń lá ní láti ṣiṣẹ́ fún Ọlọrun ní àdúgbò àwọn ilé e wọn. Wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ ní ìdákẹ́jẹ́ ẹ́ àti ní ìrẹ̀lẹ̀, kí wọn sì gbé àyíká ọ̀run pẹ̀lú u wọn níbikíbi tí wọ́n bá ń lọ. - Testimonies, vol.9, p.128.IIO 116.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents