Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI - KEFÀ ÀWỌN ỌMỌ ILÉ-Ẹ̀KỌ́ NÍ LÁTI ṢIṢẸ́ AJÍHÌNRERE LẸ́NU Ẹ̀KỌ́ṢẸ́

  Àfojúsùn nínú Ẹ̀kọ́.

  Ẹ̀kọ́ tòótọ́ jẹ́ ìkọ́ni ti òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Ọmọ Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni a pè láti jẹ́ òjiṣẹ́ Ọlọ́run; a pè wá fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti ti ẹnìkejì i wa, láti mú wa yẹ fún iṣẹ́ ìsìn yìí gbọdọ̀ ni ohun tí a gbé ka iwájú nípa ti ẹ̀kọ́ ọ wa.- The Ministry of Healing, p.395.IIO 64.1

  kí a lè dáàbòbò àwọn ọ̀dọ́ ní ìdojúkọ àwọn ìdánwò o ti ọ̀tá ni a ṣe dá àwọn ilé-ẹ̀kọ́ sílẹ̀ níbi tí ó yẹ fún ìwúlò nínú ayé yìí àti fún iṣẹ́ ìsìn ti Ọlọ́run títí ayérayé.- Counsels to teachers, p.495.IIO 64.2

  Ẹni tí ó tiraka láti wá ìmọ̀ kí ó lè ṣiṣẹ́ fún àwọn aláìnímọ̀, àti àwọn tí ń ṣègbé, ó ń ṣapá tirẹ̀ fún ìmúṣẹ ètò ń lá Ọlọ́run fún ènìyàn. Nínú iṣẹ́ ìsìn àì- mọ- tara-ẹni- nìkan fún ìbùkún àwọn ẹlòmíràn ó ń ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ kí ẹ̀kọ́ tòótọ́ ṣe. Consels to Teachers, p.545.IIO 64.3

  Ọlọ́run ń pè alágbára, olùfọkànsìn, o-ní-ṣẹ́-ra-ẹni ọ̀dọ́ lókùnrin àti lóbìnrin, tí yóò le è tẹ̀ síwájú, àti tí, lẹ́hìn ìgbà díẹ̀ tí ó lò ní ilé-ìwé, yóò le lọ gbáradì láti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí fún aráye.- Counsels to Teachers, p.549.IIO 64.4

  Àwòkọ́ṣeIIO 64.5

  Ó ṣe pataki si ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti parí pé a gbọ́dọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láàyè láti ṣe iṣẹ́ oníwàásù- àsìkò láti jẹ́ kí wọn mọ ohun tí wọn yóò bá pàdé pẹ̀lu ohun ẹ̀mí ti àwọn ìdílé nílò ní àyíká a wọn.Wọn kò gbọdọ̀ ka ìwé àkàjù débi i pé wọn kò ní ní àsìkò láti lo ìmọ̀ tí wọ́n ti kójọ. A gbọdọ̀ gbà wọ́n níyànjú láti nítara, fún iṣẹ́ ìhìnrere fún àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà, kí wọn mọ ohun tí wọn yóò bá pàdé pẹ̀lú u wọn, kí wọn gbé òtítọ́ lọ sọ́dọ̀ ọ wọn. Nípa ṣí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, wíwá ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Krístì, gbígbàdúrà kí wọn sì máa ṣóra nínú àdúrà, wọn yóò lè fún àwọn mìíràn lára ìmọ̀ tí ó fikún ìgbé ayé e wọn.- Counsels to teachers,pp.545,546.IIO 64.6

  Níbikíbi tí ó bá ti ṣe é ṣe, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀, lákókò ilé-ìwé, kí wọn kópa nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ìlú ń lá. Wọ́n gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ìhìnrere ní àwọn ìlú àti àwọn ìletò tí ó yí wọn ká. Wọ́n lè pín ara wọn sí ẹlẹ́gbẹ́ jẹgbẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìrànwọ́ ti onígbàgbọ́. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ fojú sùnùkùn wo n ǹkan àìmáṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ sí Ọlọ́run. Wọn kò gbọdọ̀ máa wo wájú sí àsìkò, lẹ́yin tí ilé-ìwé bá ti parí, nígbà tí wọn yóò ṣe iṣẹ́ ń lá fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ fiyèsí bí,lásìkò ìgbé ayé ọmọ ilé-ìwé e wọn, láti dàpọ̀ pẹ̀lu u Krístì nínú iṣẹ́ ìsìn tí kò mọ tara rẹ̀ fún ẹlòmíràn.- Counsels to teachers, p.547.IIO 65.1

  Èyí nìkan kò tó láti kún inú ọkàn àwọn ọ̀dọ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ pàtàkì; wọ́n gbọdọ̀ kọ́ láti kọ́ni ní ohun tí wọ́n ti gbà.- Counsels to Teachers, p.545.IIO 65.2

  Láti àwọn ilé-ìwé gíga a wa àti ilé-ìwé olùkọ́ni i wa àwọn ajíhìnrere ni a gbọdọ̀ rán lọ sí àwọn ilẹ̀ tó jìnnà réré. Nígbà tí wọn wà ní ilé-ìwé, jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tún gbogbo ààyè ṣe láti gbáradì fún iṣẹ́ yìí. Níbí ni a yóò ti dán wọn wò, kí wọn le mọ ohun tí àmúyẹ wọn jẹ́, àti pé bóyá wọ́n ní àbáṣepọ̀ tí ó tọ́ láti òkè.- Counsel to mTeachers, p.549.IIO 65.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents