Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn ọna Ìmọ́lẹ̀ Àti Ìbùkún.

    A níláti jẹ́ ọna tí a yà sọ́tọ̀, nínú èyí tí igbe ayé e ti ọ̀run yóò fi ṣàn sí àwọn míràn.Ẹ̀mí mímọ́ níláti sọ ni di ààyè àti láti kún gbogbo ìjọ, sọ di mímọ́ àti láti mú àwọn ọkàn wà papọ̀.-Testimonies, vol.19,p.20.IIO 18.1

    Gbogbo àtẹ̀lé e Krístì ni ó ní iṣẹ́ láti ṣe bí ajíhìnrere fún Krístì, nínú ìdílé,ní agbègbè , nínú ìlú kékeré tàbí ìlú tí ó tóbi níbi tí ó ń gbé. Gbogbo àwọn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run yóò jẹ́ orísun ìmọ́lẹ̀. Ọlọ́run sọ wọ́n di ohun èlò òdodo láti sọ fún ẹlòmíràn ìmọ́lẹ̀ òtítọ́.-Testimonies,vol.2,p 632.IIO 18.2

    Àṣeyọrí iṣẹ́ Jésù, bí ó ṣe jòkó tí àárẹ̀ mú u tí ebi sì ń paá ní etí i kànga jẹ́ ohun tí ó mu ibùkún tan ká. Ọkàn kan tí ó fẹ́ láti ràn lọ́wọ́ jẹ́ ọ̀nà láti dé àrọ́wọ́tó àwọn mìíràn àti mímú wọn lọ fún Olùgbàlà.Èyí jẹ́ ọ̀nà tí iṣẹ́ Olúwa fi ń tẹ̀ síwájú ní ayé, jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kí ó tàn, yóò si tan àwọn iná mìíràn.- Gospel Workers, p.195.IIO 18.3

    Ọ̀pọ̀ ní òye pé àwọn ní láti jíhìn bí ìríjú fún Krístì nìkan fún ìmọ́lẹ̀ wọn àti ìrírí i wọn, láì fi ti àwọn àtẹ̀lé e RẸ̀ tí a mọ̀ láyé ṣe.Jésù jẹ́ ọ̀rẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ọkàn an rẹ̀ sì tọ̀ wọ́n lọ nìnù ègbé e wọ̀n, ó ní gbogbo agbára, ní ayé àti ní ọ̀run, ó bọ̀wọ̀ fún ọ̀nà pé a ti fi àmì òróró yàn fún ìfini mọ̀nà àti ìgbàlà ènìyàn, ó ǹ tọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ilé Ọlọ́run, èyí tí ó sì ti fi ṣe orísun ìmọ́lẹ̀ sí aráyé.- The Acts of the Apostles, p.122.IIO 18.4

    Iṣẹ́ tí ó n fi lemọ́ lemọ́ tan ka ni a ti gbé síwájú àwọn ìjọ ìṣáájú- láti ṣe ìfi lọ́lẹ̀ àwọn ibudo ìmọ́lẹ̀ àti ìbùkún níbikíbi tí àwọn ọkàn tí ó jẹ́ olóòótọ́ ti ń fẹ́ láti fi ara a wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ Ọlọ́run.- The Acts of the Apostles, p.90IIO 18.5

    Bí ìtànṣán oòrùn ṣe ń wọ àwọn ibi tí ó farasin káàkiri àwọn orígun ayé, bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run dárà pé ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere gbọdọ̀ tàn sí ọkàn kọ̀ọ̀kan nínú ayé.Tí ìjọ Krístì mú Olúwa ṣẹ, ìmọ́lẹ̀ yóò tàn sí àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn,ní agbègbè àti òjìji ikú.- Thought from the Mount of Blessing, p. 42.IIO 18.6

    Ànfààní ni ó jẹ́ fún ọkàn kọ̀ọ̀kan láti jẹ́ orísun ààyè tí Ọlọ́run lè fi bá aráyé sọ̀rọ̀ ìṣúra oore ọ̀fẹ́ ẹ RẸ̀, ọrọ̀ tí o kò le ṣàwárí nínú Krístì. Kò sí ohun tí ó wu Kristi bíi aṣojú fún ẹmí àti ìwà a RẸ̀ sí araye.Kò sí ohun tí ayé nílò tó bẹ́ẹ̀ bí ìfarahàn nípasẹ̀ ènìyàn sí ìfẹ́ Olùgbàlà.Ohun ti ọ̀run n ´dúró dè ni orísun tí a lè lò alti tu ororo mimọ ti yoo jẹ ayọ ati ibukun si ọkan eniyan.-Christ Object Lessons, p.419.IIO 19.1

    Ògo ìjọ Ọlọ́run wà nínú iwa mimọ ọmọ ìjọ nítorí, ibẹ̀ ni agbára Ọlọ́run farasin sí.Ipa àwọn ọmọ Ọlọrun tòótọ́ ni a le wò bí ohun tí kò níye lórí,a yóò rí ipa a rẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà, a yóò sì ṣe ìfihàn-an rẹ̀ nítòótọ́ ní ọjọ́ ìpín èrè fúnni. Ìmọ́lẹ̀ onígbàgbọ́ tòótọ́, yóò tàn ní ìdúró ṣinṣin ìwà mímọ́, ìgbàgbọ́ tí kò ṣiyèméjì, yóò ṣe ìfihàn agbára Olùgbàlà tó wà láàyè fun aráyé. Nínú àwọn àtẹ̀lé e RẸ̀, a máa fi Krístì hàn bíi kànga omi, tí ó ńsun jáde sí ìyè àínìpẹkun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kó di mímọ̀ fún ayé, wọ́n mọ̀ wọ́n sí ènìyàn ọ̀tọ̀, àwọn ọ̀nà sí ìgbàlà, orísun rẹ̀ níbi tí ìmọ́lẹ̀ ti máa wá sí ayé. - Reẹiew, March 24, 1891.IIO 19.2

    Ẹ̀yin ọmọ ìjọ, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín tàn, ẹ jẹ́ kí ohuǹ yín di gbígbọ́ nínú àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ yín, ní ìjẹ́rìí sí títako àìníwọ̀n túwọ̀nsì, wèrè àti ohun mèremère ayé yìí, àti nínú pípolongo òtítọ́ fún ìsinsinyìí.Ohùn rẹ, ọlá à rẹ, àsìkò o rẹ-gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a sì gbọdọ̀ ló wọ́n ní jíjèrè àwọn ọkàn fún Ọlọ́run.-Testimonies, vol.9, p.38.IIO 19.3

    A ti fi hàn mí pé àwọn àtẹ̀lé Krístì ni aṣojú rẹ̀ ní ayé; Ọlọ́run ṣètò pé wọn yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ láarin ayé tí ó kún fún ìwà òkùnkùn, tí ó wa káàkiri ní orílẹ̀èdè, nínú ìlú,nì àwọn ìletò,àti ìlú ń lá ń lá, ” fún wíwò aráyé, sí àwọn ángélì àti sí ènìyàn.”- Testimonies, vol.2, p.631.IIO 19.4

    Àwọn àtẹ̀lé e Krístì ní láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayé;ṣùgbọ́n kò sọ fun wọ́n láti gbìyànjù láti tàn.Akitiyan ìtẹ́ra ẹni lọ́rùn tí ń ṣàfihàn mogbọ́n tán mo mọ̀ tán ni kò ní ìtẹ́wọ́gbà níwájú u RẸ̀. Ó fẹ́ pé kí ọkàn wọn wà ní ìbámu pẹ̀lu àwọn àgbékalẹ̀ ọ̀run; lẹ́yìn èyí, bí wọ́n sì ṣe ń bá àwọn ayé pàdé, wọn yóò fi ìmọ́lẹ̀ tí ó wà nínú u wọn hàn.Ìdúró ṣinṣin nínú ìwà mímọ́ ọ wọn yóò jẹ́ orísun ìmọ́lẹ̀.-The Ministry of Healing, p.36.IIO 19.5

    Nígbà tí ó wà nínu ifójú iṣina àti èrò búburú àìnídìí, Sọ́ọ̀lù rí ìran Krístì èyí tí ó ń ṣe inúnibíni sí, a fì si ìbánisọ̀rọ̀ ojúkoojú pẹ̀lú ìjọ, èyí tíí ṣe ìmọ́lẹ̀ ayé; Fún ìdí èyí, Ananáyà dúró fún Krístì, ó sì tún dúró fún àlùfáà Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé tí ó yàn láti ní ipò o rẹ̀.Dípò Krístì, Ananáyà f’ọwọ́ kan Sọ́ọ̀lù, kí ó baà lè ríran,Dípò Jésù ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lèe, bí ó sì ti gbàdúrà ní orúkọ Jésù Ṣóọ̀lù gba ẹ̀mi mímọ́. Gbogbo èyí ní orúkọ àti àṣẹ ti Krístì. Krístì ni ìpìlẹ̀, ìjọ sì ni ọ̀nà ìbáni sọ̀rọ̀.- The Acts of the Apostles, p.122.IIO 20.1

    Ìṣìnà ń borí ní ibi gbogbo, akọni ọ̀tá ẹ̀mí i nì, ń kó ogun rẹ̀ jo. ó ń lo ọ̀kọ̀ọkan ọ̀gbọn àyínìke e rẹ̀ láti mú ọkàn àwọn ènìyàn pòruurù pẹ̀lú àwọn ẹ̀tàn iṣina, àti láti mú kí àwọn ọkàn ṣègbé.Àwọn tí Ọlọ́run ti fi ìṣúra òtítọ́ ọ rẹ̀ sí ìkáwọ́ wọn lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ẹ wọn tàn láarin àwọn ìwà òkùnkùn.- Historical Sketches, p.290.IIO 20.2

    Ọlọ́run ǹ fẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ tàn bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé. Kì í ṣe àwọn àlùfáà ni ó níláti ṣe èyí, ṣùgbọ́n àtẹ̀le e Krístì kọ̀ọ̀kan, Ìbaniṣọrọ ọ wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti ọ̀run, bí wọ́n sì ṣe ń gbádùn ìdàpọ̀ pẹ̀lú ọ̀run, wọn á fẹ́ láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú arákùnrin wọn, láti fihàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ ọ wọn àti láti fi ìfẹ́ ẹ RẸ̀ ṣe ìwà hù èyí tí yóò sọ ọkàn-an wọn di ààyè.Ní ọ̀nà yìí,wọn yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ nínú ayé, ìmọ́lẹ̀ náà tí ó tàn nípasẹ̀ ẹ wọn kì yóò di òkùnkùn bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gbà á kúrò lọ́wọ́ ọ wọn.- Testimonies, vol.2, pp.122, 123.IIO 20.3

    Àtẹ̀lé e Krístì gbọdọ̀ jẹ́ ohun èlò òdodo, òṣìṣẹ́, òkúta ààyè, imọlẹ titan,kí wọn lè jẹ́ kóríyá fún ìwàláarin wọn ti àwọn ángẹ́lì ọ̀run. Wọ́n fẹ́ kí wọn jẹ́ àwọn ọ̀nà bí ó ṣe wà nípasẹ̀ ẹ bí ẹ̀mi òtítọ́ àti òdodo yóò ṣe ṣàn.-Testimonies,vol.2,pp.126,127.IIO 20.4

    Ọlọ́run ti fi ìjọ rẹ̀ ṣe ibi ìṣúra fún ipa ti ọ̀run.Àwọn ọ̀run sì ń dúró de àwọn ọmọ ìjọ láti jẹ́ àwọn ọ̀nà ńinú èyí tí ìmọ́lẹ̀ ìyè yóò sàn sí ayé, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ le è ní ìyípadà ọkàn, tí àwọn náà yóò fi lè jẹ ọna ti oore-ọ̀fẹ́ ẹ Jésù yóò fi ṣàn sí abala àwọn aṣálẹ̀ tí ó wà ní ọgbà àjàrà Olúwa.-Bible Echo, Aug.12, 1901.IIO 21.1

    Ọlọ́run ti yan àwọn ọmọ rẹ̀ láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn mìíràn, tí wọ́n bá sì kọ̀ láti ṣe é tí a sì fi àwọn ọkàn sílẹ̀ sínú òkùnkùn ti ìṣìnà nítorí bíbàkù láti ṣe ohun tí ó yẹ kí wọn ti ṣe, kì bá jẹ́ pé a ti fi agbara fún wọ́n ńipa ẹ̀mí mímọ́, wọn yóò jíyìn fún Ọlọ́run.A ti pè wá láti inú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀, láti lè máa fi ìyìn Krístì hàn.-Reiew and Herald, Dec.12, 1893.IIO 21.2

    Àwọn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run yóò jẹ́ bí orísun ìmọ́lẹ̀. Ọlọ́run sọ wọ́n di aṣojú tí yóò bá àwọn mìíran sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́….Ipa a wa lórí àwọn mìíran kò fi bẹẹ dúró lórí ohun tí a sọ, bí i dídúró lórí ohun tí a jẹ́. Ènìyàn lè ṣe àtakò àti àìnáání sí ọgbọ́n èrò o wa, wọ́n le è kọ àwọn ìpàrọwà a wa; ṣùgbọ́n ìgbésí ayé ìfẹ́ àìṣègbè ni ohun tí wọn kò le è ṣàì náání. Ìgbésí ayé ìdúró ṣin- ṣin tí ó ní àfarawé e ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ẹ ti Kristi, jẹ́ agbára nínú ayé.-The Desire of Ages, pp.141, 142.IIO 21.3

    Àwọn tí ó yẹ kí ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayé ti jẹ́ bí aláìlera ati olókùnrùn.Kíni ìmọ́lẹ̀? Ó jẹ́ ìbọ̀wọ̀ fún, Ìṣoore, òtitọ́, àánú, ìfẹ́; Ó jẹ́ ìṣàfihàn òtítọ́ nínú ìwà àtí ìgbé ayé. Ìhìnrere náà sì dúró lórí i ìbọ̀wọ́ fún tí àwọn onígbàgbọ́ fún agbára, Ọlọ́run ti pèsè nípasẹ̀ ikú ọmọ ọ rẹ̀, pé kí ọkàn leè wà ní iṣẹ́ rere. Ọkàn kọ̀ọ̀kan ní láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀, tí ó ń tàn tí ó sì ń fi ìyìn Ọlọ́run tí ó ti pè wọ́n kúrò nínú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn. “a jẹ́ alábàá ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run”. Bẹ́ẹ̀ni, alágbàṣe; tí ó túmọ̀ sí ṣiṣẹ́ ìtara nínú ọgbà àjàrà Ọlọ́run. Ọkàn àwọn tí a lè gbàlà wà.Ọkàn nínú ìjọ, nínú ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi wa, àti ní àdúgbò o wa. Review and Herald, March 24, 1891.IIO 21.4

    Nínú ṣí ṣiṣẹ́ fún ẹlòmíràn, wọ́n ti sọ ọkàn ẹlòmíràn jí. Tí wọ́n bá jẹ́ alábà à ṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú u Jésù, a máa rí ìmọ́lẹ̀ nínú ìjọ wa tí ó ń tàn tí ó sì ń jò geere, tí ó sì ń tán ìtànsán an rẹ̀ sí inú òkùnkùn kọjá agbègbè e wọn.-Historical Sketches, p.291.IIO 22.1

    “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé”. Àwọn Júù rò láti fi àwọn ànfààní ti ìgbàlà han àwọn orílẹ̀-èdè wọn, ṣùgbọ́n Krístì fihàn wọ́n pé ìgbàlà dàbí oòrùn tí ó ń ràn tí ó sì jẹ́ ti gbogbo àgbáyé. - The Desire of Ages, p.306.IIO 22.2

    Àwọn ọkàn tí ó dáhùn sí ipa ti ẹ̀mí mímọ́ ni wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀nà ti ìbùkún Ọlọ́run tí ń ṣàn. Ki bá jẹ́ pé a mu awọ́n ti wọn ń sin Ọlọ́run kúrò láyé, tí a sì mú ẹ̀mí i RẸ̀ kúrò láarin àwọn ènìyàn, ohun ti yoo ku fun ayé ni ìsodahoro àti ìparun, eso ìṣèjọba Sàtánì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pè àwọn olùṣe búburú kò mọ̀, wọ́n ń jẹ ànfààní ìbùkún ayé yìí nítorí àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí wọ́n ń gan tí wọ́n sì ń pọ́n lójú.Ṣùgbọ́n tí àwọn Krìstẹ̀ẹ́nì bá jẹ́ kìkì orúkọ nìkan, wọ́n dàbí iyọ̀ tí ó ti sọ adùn- un rẹ̀ nù. Wọn kò ní ipa rere nínú ayé. Nípa àì má ṣe aṣojú Ọlọ́run, wọ́n burú ju àwọn aláìgbàgbọ́ lọ. - The Desire of Ages, p. 306.IIO 22.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents