Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ìdàpọ̀ Ìsọjí i Ti Ẹ̀mí Àti Iṣẹ́ Ọlọ́danni

  Nígbà tí ìjọ bá sọjí, yóò jẹ́ nítorí pé àwọn ènìyàn kan ni wọ́n ´ìbùkun Ọlọ́run pẹ̀lú ìtara. Ebi ń pa á òrùgbẹ sì ń gbẹ ẹ́ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Ó sì ń bèrè pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ó sì ń gbà á bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ó ń lọ sí ibi iṣẹ́ pẹ̀lú ìtara, ó ní ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó tóbi lórí Ọlọ́run, àwọn ọkàn sì gbé sókè láti wá irú ìbùkún bẹ́ ẹ̀, àti àkókò ìtura yóò rọ̀ sórí àwọn ọkàn àwọn ènìyàn.Ìlọsíwájú iṣẹ́ náà kò ní di àìfiyèsí. Ìlànà tí ó tóbi ni a yóò là kalẹ̀ ní àsìkò tí ó tọ́; ṣùgbọ́n ìgbìy/ànjú olúkúlùkù àti ìfẹ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládúgbò, yóò ní àṣeyọrí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju èyí tí a le è ṣírò. Wíwá irú iṣẹ́ bí èyí li ó ń mú kí àwọn ọkàn tí Krístì kú fún ṣègbé. (Corect)IIO 121.1

  Ọkàn kan níye ainipẹkun lórí; nítorí Kálfárì ń sọ bí ó ṣe jẹ́ iyebíye tó. Ọkàn kan, tí a jèrè fún òtítọ́, yóò jẹ́ ohun èlò nínú jíjèrè àwọn ẹlòmíràn. Ìyọrísí tí yóò má a fi ìgbà gbogbo tẹ̀síwájú níti ìbùkún àti ìgbàlà ni a yóò rí. Iṣẹ́ ẹ̀ rẹ le è mú èso rere wá ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpàdé pípẹ́ lọ, tí wọn bá ṣe aláìní ìgbìyànjú lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Nígbá tí a bá kó wọn jọ pọ̀, pẹ̀lú ìbùkún Ọlọ́run, iṣẹ́ tí ó péye jù tí ó dára ni yóò jẹ́ ṣíṣẹ; ṣùgbọ́n tí apákan bá jẹ́ ṣíṣe, jẹ́ kí ó jẹ́ iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ṣí ìwé mímọ́ ní àwọn ìdílé, tí yóò pàrọwà bí ọlọ́danni, tí yóò sì sọ̀rọ̀ bí ẹni tí kì í ṣe àjèjì sí ìdílé, kì í ṣe nípa àwọn n ǹkan tí kò fi bẹ́ ẹ̀ ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n níti àwọn àkórí ọ̀rọ̀ ń lá a ti ìràpadà. Jẹ́ kí wọn rí i pé ọkàn- àn rẹ wúwo fún ìgbàlà àwọn ọkàn.-Review and Herald, March 13, 1888.IIO 121.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents