Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Dídàpọ̀ Mọ́ Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìhìnrere

    Iṣẹ́ ihinrere àti onìṣègùn ajihinrere ni ó ní láti tẹ̀ síwájú papọ́. Ìhinrere ni a ní láti dìpọ̀ pẹ̀lú ìpìlẹ̀ àtúnṣe àwọn elétò ìlera tòótọ́. Ìsìn onígbàgbọ́ ni a ní láti mú wá sínú ìgbé ayé tí ó wúlò. Ìtara, ohun tótó, a sì ní láti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe….A ní láti ṣe àgbékalẹ̀ àtúnṣe ètò ìlera níwájú àwọn ènìyàn, kí a ṣe ohun gbogbo tí ó wà ní agbára a wa láti darí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin láti rí àìgbọdọ̀ máṣe àwọn ìpìlẹ̀ yìí àti láti mú wọn lò.- Testimonies, vol.6, p.379.IIO 133.5

    Àgbékalẹ̀ ẹ ti ọ̀run ni pé a yóò ṣiṣẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀hìn ṣe ṣiṣẹ́. Ìwòsàn-an ti ara ni a papọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ ìhìnrere tí a fifún ni. Nínú iṣẹ́ ihinrere, ìkọ́ni àti ìwòsàn ni a kò yà sọ́tọ̀ rárá.- The Ministry of Healing, p.141.IIO 133.6

    Iṣẹ oníṣègùn ajihinrere àti iṣẹ́ iranṣẹ ihinrere jẹ́ àwọn orísun èyí tí Ọlọrun ń wá láti da ìpèsè ìṣoore e RẸ̀ tí kò yípadà lé lórí. Wọn ní láti jẹ́ bí odò ààyè fún bíbominrin ìjọ ọ RẸ̀.- Bible Echo, Aug.12, 1901.IIO 133.7

    Jẹ́ kí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun wa, tí wọ́n ní ìrírí nínú u wíwàásù ọ̀rọ̀,kọ́ bí wọ́n ṣe le ṣe ìtọ́jú lọ́nà tí ó rọrùn, kí wọn sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òye bí àwọn oníṣègùn ajíhìnrere ojiṣẹ Ọlọrun.- Testimonies, vol.9, p.172.IIO 134.1

    Bì àwọn òǹtàwé ṣe ń lọ láti ibìkan dé ibìkejì, yóò rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ń ṣe àìsàn. Ó gbọdọ̀ ní ìmọ̀ tí ó wúlò nípa ohun tí ó fa àìsàn, ó sì gbọdọ̀ ní òye bí óọṣe ìtọ́jú ní ọ̀nà tí ó rọrùn, kí ó ba à lè mú ìdẹ̀ra bá àwọn tí ó wà nínú ìrora. Ju eléyìí lọ, o gbọdọ̀ gbàdúrà pẹ̀lu ìgbàgbọ́ àti inú kan fún aláìsàn, kí ó sì tọ́ka a wọn sí oníṣègùn ń lá náà. Bí ó ṣe ń rìn tí ó sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọrun, àwọn ańgẹ́lì òjíṣẹ́ wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀, tí wọ́n ń fún un ní ààyè láti wọnú àwọn ọkàn.Kín ni pápá ń lá fún ìgbìyànjú ajihinrere tí ó wà níwájú u olóótọ́, òǹtàwé tí ó ya ara a rẹ̀ sí mímọ́; irú ìbùkún wo ni yóò rí gbà nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀ tí ó ṣe láìsinmi. - Southern Watchman, Nov.20, 1902.IIO 134.2

    Iranṣẹ Ọlọrun kọ̀ọ̀kan ni ó ní láti mọ̀ pé fífún ni ní ẹ̀kọ́ nínú àwọn ìpìlẹ̀ ti ìgbé ayé ìlera, jẹ́ ara iṣẹ́ tí a yàn fún un láti ṣe. Nínú iṣẹ́ yìí ohun ń lá ni a nílò, ilé ayé sì ṣí sílẹ̀ fún un.- The Ministry of Healing, p.147.IIO 134.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents