Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìjẹ́wọ́ Pẹ̀lú Ìhùwà

    Olúkúlùkù òtítọ́ tí ó ṣe pàtàkì tí a gbà sínú ọkàn gbọdọ̀ hàn nínú ìsọ̀rọ̀ nínú ìgbé ayé. Ó jẹ́ òṣùwọ̀n sí gbígba ìfẹ́ ẹ ti Krístì pé kí ènìyàn nífẹ̀ ẹ́ láti polongo agbára a rẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn; àti nínú ìṣè polongo o rẹ̀, yóò jinlẹ̀ yóò sì jẹ́ kí ìwúlò o rẹ̀ jẹ́ kíákíá nínú ọkàn àwọn fúnra ara wọn.- Review and Herald, Feb.19, 1889.IIO 94.4

    Ìgbàgbọ́ ọ wa gbọdọ̀ kún fún àwọn iṣé rere; nítorí pé ìgbàgbọ́ láì sí iṣẹ́ jẹ́ òkú. - Testimonies, vol.4, p.145.IIO 95.1

    Gbogbo ẹni tí ó gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ìhìnrere sínú ọkàn an wọn ni yóò fẹ́; láti polongo o rẹ̀. Ìfẹ́ tí a bí mọ́ Krístì láti ọ̀run gbọdọ̀ hàn nínú sísọ̀rọ̀. - Christ’s Object Lessons, p.125.IIO 95.2

    A ní láti yin Ọlọ́run pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn tòótọ́, nípa sísa agbára a wa láti tẹ ògo ti orúkọ RẸ̀ síwájú.- Christ’s Objẹct Lessons, p.300.IIO 95.3

    Ìgbàgbọ́ ọ wa ní àsìkò yìí kò gbọdọ̀ dúró pẹ̀lú ìjẹ́wọ́ sí tàbí gbàgbọ́ nínú, nínú ìmọ̀ tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ańgẹ́lì kẹ́ta. A gbọdọ̀ ní òróró o ti oore-ọ̀fẹ́ ẹ ti Krístì tí yóò má a bọ́ àwọn agbo, tí yóò sì mú kí ìmọ́lẹ̀ ìyè jáde, tí yóò sì fi ọ̀nà han àwọn tí ó ti wá l’óòkùn. - Testimonies, vol.9, p.155.IIO 95.4

    Agbára ẹ̀mí i rẹ̀ àti ìbùkún ni yóò jẹ́ òṣùwọ̀n sí iṣẹ́ ìfẹ́ àti àwọn iṣẹ́ rere tí a ti ṣe. - Testimonies, vol.3, p.52.IIO 95.5

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ni a le ṣe fún Krístì tí gbogbo àwọn tí ó ní ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ yóò bá hùwà a ti òtítọ́. - Testimonies, vol.9, p.40.IIO 95.6

    A fihàn mí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn a jẹ́ alábùkù. Àwọn iṣẹ́ ẹ wa kò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ọ wa. Ìgbàgbọ́ ọ wa jérì í sí i pé à ń gbé ní abẹ́ ìpolongo ohun mímọ́ jùlọ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Pàtàkì tí a ti fún àwọn ènìyan alára kíkú. Síbẹ̀ nínú èrò tí ó kún tí ó sì dájú yìí, àwọn ìgbìyànjú, àwọn ìtara a wa, àwọn ẹ̀mí ìfara ẹni rúbọ, ni a kò le fiwé pẹ̀lú ìwà àti iṣẹ́. A gbọdọ̀ tají kúrò nínú ipò òkú, Krístì yóò sì fún wa ní ìyè.- Testimonies, vol.2, p.114.IIO 95.7

    Ẹ lọ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, kí ẹ polongo òtítọ́ náà bíi pé ẹ gbà á gbọ́. Jẹ́ kí àwọn tí ó ṣiṣẹ́ fún rí i pé ẹ̀yin fúnra a yín lótítọ́ gbé ìgbé ayé tí ó jẹ́ òtítọ́.- Testimonies, vol. 9, p. 42.IIO 95.8

    Ìgbé ayé e wa bí i Krístì ni ó jẹ́ àríyànjiyàn tí ó lágbára jù tí a lè fi tẹ̀síwájú ní ojú rere sí ìsìn Krístì.- Testimonies,vol.9, p.21.IIO 95.9

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ Krístì tí ọkàn an wọn kò sí nínú iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n ti wọ ara wọn láṣọ nínú ìjẹ́wọ́ ti ìwà bí Ọlọ́run, àti nípa ṣíṣe èyí wọ́n ti mú kí ìdálẹ́bi wọn pọ̀ si, wọ́n sì ti di atanijẹ àti àwọn aṣojú aláṣeyọrí i ti ẹ̀ṣù nínú u pípa àwọn ọkàn run.- Review and Herald, March 27, 1888.IIO 95.10

    Gbogbo àwọn tí wọ́n ń ṣọ́nà fún Olúwa, ni wọ́n ti sọ ọkàn an wọn di mímọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́ náà. Síṣọ́ra pẹ̀lú ìṣọ́nà ni wọ́n papọ̀ mọ́ iṣẹ́ ìtara. Nítorí pé wọ́n mọ̀ pé Olúwa wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn, ìtara a wọn ni a sọjí láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀run nínú ṣíṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn ọkàn náà, Àwọn wọ̀nyí ni olódodo àti àwọn ìránṣẹ́ ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ń fi sílẹ̀ sí ilé Olúwa “Yóò sì fún wọn ní oúnjẹ ẹ wọn l’ásìkò.” Wọ́n ń sọ òtítọ́ ti ìgbà yìí tí ó bá wa mu. Bí i Énọ́ọ̀kù, Nóà, Ábráhámù àti Mósè ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni ó kéde òtítọ́ náà fún àsìkò o tiwọn, ṣé àwọn ìránṣẹ́ ẹ Krístì ní àsìkò yìí yóò fi ìkìlọ̀ pàtàkì yìí fún àwọn ìran an wọn.- The Desire of Ages, p.634.IIO 96.1

    Dídúró o wa níwájú Olúwa dúró, kìí ṣe lórí ìmọ́lẹ̀ tí a gbà, ṣùgbọ́n lórí bí a ṣe lo ohun tí a ní. Báyìí àwọn kèfèrí pàápàá tí wọ́n yan ohun tí ó tọ́ tí wọ́n sì mọ ìyàtọ̀ ọ rẹ̀, ni wọ́n wà ní ipò ìrọ̀rùn ju àwọn tí wọ́n ní ìmọ́lẹ̀ ń lá, tí wọ́n jẹ́wọ́ láti sin Ọlọ́run, Ṣùgbọ́n tí wọn kò ka ìmọ́lẹ̀ náà sí, tí ìgbé ayé e wọn ojoojúmọ́ tako ohun tí wọ́n jẹ́wọ́.- The Desire of Ages, p.239.IIO 96.2

    Ànfààní ni ó jẹ́ fún onígbàgbọ́ kọ̀ọ̀kan láti máṣe wò nìkan ṣùgbọ́n láti mú kí bíbọ̀ Olúwa Jésù Krístì tètè dé. Ki bá jẹ́ pé gbogbo àwọn tí ó jẹ́wọ́ orúkọ ọ RẸ̀ ni wọ́n ń so èso fún ògo o RẸ̀, ní kíákíá ni à bá ti fúrúgbìn èso ti ìhìnrere ká gbogbo àgbáyé. Ní kánkán àsìkò ìkórè ń lá ikẹ́hìn yóò dé, Jésù yóò si wá láti kó àwọn irúgbìn tí ó ṣe iyebíye jọ.- Christ’s Objẹct Lessons, p.69.IIO 96.3

    Ẹ̀yin onígbàgbọ́ gbọdọ̀ jí fúnra a yín, kí ẹ sì gbé àwọn iṣẹ́ tí ẹ fojú fò; nítorí ìgbàlà ọkàn an wọn dúró lórí àwọn ìgbìyànjú ẹnìkọ̀ọ̀kan an wọn.- Review and Herald, Aug. 23, 1881.IIO 96.4

    Ìsìn tòótọ́ dúró nínú u sí ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú u Krístì. Àdúrà, ọ̀rọ̀ ìyànjú, àti ìsọ̀rọ̀ jẹ́ àwọn éso tí ó gbọ̀pọ̀ tí a sì ń so mọ́ ní gbogbo ìgbà; Ṣùgbọ́n àwọn èso tí ó farahàn nínú iṣẹ́ rere, nínú u títọ́jú àwọn aláìní, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó ni wọ́n jẹ́ ojúlówó èso, tí wọ́n ń so nípa ìṣẹ̀dá lórí igi rere.- Review ahd Herald, Aug.16,1881.IIO 96.5

    Jẹ́ kí àwọn ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan gbé iṣẹ́ tí a yàn wọ́n nípa títàn ká àti nípa gbígba ìmọ́lẹ̀, kò sí ẹnìkan tí ó rí àwáwí ṣe nínú u ṣíṣe ìmẹ́lẹ́ nínú ọgbà àjàrà Olúwa.- Review and Herald, Feb.19, 1889.IIO 96.6

    Ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tó níṣe náà ni èso ti krístì fẹ́ kí a so. Ṣíse iṣẹ́ ìtọrẹ àánú, sísọ àwọn ọ̀rọ̀ rere jáde, ṣíṣe àfihàn ìtùnú nípa bíbìkítà fún òtòṣì, aláìní, àwọn tí a pọ́n lójú.- Review and Herald, Aug.16, 1881.IIO 97.1

    Láìpẹ́, láìjìnà tí obìnrin ará Samáríà náà tí ó ń bá Jésù sọ̀rọ̀ ní etí kànga Jákọ́bù rí Jésù ló mú àwọn mìíran wá sí ọ̀dọ̀ ọ RẸ̀. Ó jẹ́rìí ara a rẹ̀ bí ajíhìnrere aláṣeyọrí ju àwọn ọmọ ẹ̀hìn in Rẹ̀ lọ. Àwọn ọmọ ẹ̀hìn kò rí ohun Kankan ní Samáríà láti fihàn pé ó jẹ́ ilẹ̀ tí ó wúni lórí. Gbogbo èrò o wọn wà lórí iṣẹ́ ń lá tí wọn yóò ṣe ní ọjọ́ iwájú. Wọn kò rí i pé ní àyíká a wọn ni ìkórè tí wọn ní láti kójọ wà, Ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ obìnrin tí a ti kẹ́gàn gbogbo ìlú ń lá tí ó kún ni ó mú wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ Jésù. Ó gbé ìmọ́lẹ̀ lọ́gán tọ àwọn ará ìlú u rẹ̀ lọ. Obìnrin yìí dúró fún ìgbàgbọ́ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú u Krístì. - The Ministry of Healing, p.102.IIO 97.2

    Àwọn Onírètí Bíbọ̀ ọ Jésù ń tẹ̀ síwájú, wọ́n ń pọ̀ si ní iye, wọ́n ń dá àwọn ilé iṣẹ́ ìhìnrere sílẹ̀, wọ́n sì ń ta àsìá òtítọ́ ní ibi òkùnkùn ayé; síbẹ̀síṣẹ̀ iṣẹ́ náà kò yára tẹ̀síwájú bí Ọlọ́run ṣe ń fẹ́ ẹ. (Báwo ni èyí ṣe rí bẹ́ ẹ̀?) Àwọn ọmọ ìjọ náà kò tají l’ẹ́nìkọ̀ọ̀kan láti lọ pẹ̀lú ìtara ìgbìyànjú tí wọn lágbára láti ṣe àti gbogbo ẹ̀ka ti iṣẹ́ ni a ti sọ di arọ nípa àìbọ̀wọ̀ fún tó, nípa àìfọkànsìn, ìrẹ̀lẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó níbẹ̀rù Ọlọ́run. Níbo ni àwọn ọmọ ogun àgbélébù ú ti Krístì wà? Jẹ́ kí àwọn tí ó níbẹ̀rù Ọlọ́run, olóótọ́, ọlọ́kàn kan, tí wọ́n ti ń wò ní ìdúró ṣinṣin níti ògo Ọlọ́run, gbáradì láti jìjàkadì tako àṣìṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ ni àwọn tó ń dákú ti ọkan-an wọn si ń ṣojo ní wákàtí ìjà a ti ẹ̀mí yìí. Báwo ni ìbá ti dára tó kí wọn di alágbára nínú àilera wọn, kí wọn sì di akọni lójú ìjà, kí wọn sì mú àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ sá.-Historical Skẹtches, p.290.IIO 97.3

    Ilànà gbo-gbo-gbò ni pé nígbàkúùgbà tí ènìyàn bá kọ̀ láti lo àwọn agbára tí Ọlọ́run fifún-un àwọn agbára yìí yóò díbàjẹ́ yóò sì ṣègbé. Òtítọ́ tí a kò lò, tí a kò sì fifún ni, ń sọ agbára rẹ̀ tí í fúnni níyè nù, àti ìwà ìmúláradá a rẹ̀ nù. - The Acts of the Apostles, p.206.IIO 97.4

    Kò sí ohun tí ó lè fi okun àti agbára fún ìfọkànsìn bí i sí ṣiṣẹ́ fún ipa tí ó jẹ́wọ́ ifẹ́ ẹ rẹ̀ dípò kí o ṣe idènà a rẹ̀. - Testimonies, vol.4, p.236.IIO 98.1

    Àwọn tí wọ́n ń sánà láti gbe ìgbé ayé ìgbàgbọ́ pẹlu fifi aiṣiṣẹ gba àwọn ìbùkún tí ó wà nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́, àti làìṣe ohunkohun fún Krístì, jẹ́ gbígbìyànjú láti jẹ láì ṣiṣẹ̀. Bi o ṣe ri nínú ohun ti ẹ̀mí bí ó ṣe wà nínú ìṣèdá, àyọrísí eléyì í jẹ́ ìdibàjẹ́ àti ìjẹrà.- Christ’s Object Lessons, p.85.IIO 98.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents